Òsé Òtúrá (EKO) Pánsá ojú iná, a bara dúdú petepete Òbùn ló t’oko bò ló rí sìàsìà D’ifá fún olúsólè Ní’jó ti ó nmú omi ojú sùnráhùn omo Ìgbàtí yó ò bí, ó bí oká Ó bí eré Ó bí Òpòló Ó bí Òjòlá Ó bí Gùntéré Ekó ni nse omo íkéhin won lénje-lénje Ekó wá s’awo re àpá òkun, ìlàmejì òsà Ìgbàtí yó ò dé, kò bá Baba mó Ó ní, “níbo ni Baba lo?” Wón ní Baba ti sósún Ó wá to àwon Babaláwo lo Wón ní ebo ni ko se, pé yó ò rí Babá a rè Ekò rú’bo Àwon Babaláwo ré fun ní eyo kòòkan nínú ohon ebo kí ó lo fi bo bàbá ré Wón ní ti ó bá ti bo Bàbá rè tán, kí ó ma wá baba lo Ekò búrín gàdà, ó pádé ilá pékí l’ónà Ilá ní omo olóore òun, “níbo ni ò nlo?” Ekó ní òun nwá baba lo Ilá fun ni ogún òké owó Ekó búrín gàdà, ó pàdé Ikàn l’ónà Ikán ni omo olóore òun, “níbo ni ò nlo?” Ekó ní òun nwá baba lo Ikán fun ni ogbón òké owó Ekó búrín gàdà, ó pàdé Olóbengán l’ónà Olóbengán ni omo olóore òun, “níbo ni ò nlo?” Ekó ní òun nwá baba lo Olóbengán fun ni ogbón òké owó Ekó tún bùrín gàdà, ilé pin níwájú, ó pin l’éhìn Ìgbàtí yó ò gbé esé ‘kíní, gbé esé ìkejì, ti yó ò gbé ìkéta, ó jín sí agbede òrun Wón ní, “ògbò nrún” Bàbá a ré ní, “ògbò kò rún” ó ní, omo òun ni Ó ní, “kíló dé ti ó fi nwá òun bòwá?” Ekó ní nígbàtí óun dé’lé, ni wón ní ó ti wá síhìín Ò ní, “Oká ti j’ogún oró” Ó ní, “Ojòlá ti j’ogún òhun” Ó ní, “Opòló j’ogún éwú ifán” Ó ní, Agùnsóóró j’ogún sísán” Ó ní, wón ní ti òun bá súnmo won, àwon yó gbé òun mì Bàbá a rè bá so àse kansoso tí ó ní kù, sí Ekó ní enu Ó ní kó kálo Ó bá bèrè sí fi gbogbo áwon nkan ti Ekó fi rú’bo l’óde ayé hàa án Ó ní ti Ekó bà dé’lé ayé Kí Ekó wí fun won pé Kí wón pa Oká ní àpa dàri Kí wón ma fi òpá tééré já ìrù Gùntéré Kí wón pa Òpòló, kí wón ma t’ojú ré bo erè Ó ní ti ó bá dé’lé ayé Ti ó bá kan odó nlá ti kò bá lé lo Ó ní ti ó bá ti fi enu so bèbè ìhín, yó ma bá ara rè ní bàbà òhún Ti ó bá kan igi nlá Ó ní ti ó bá ti fi enu so bèbè ìhín, yó ma bá ara rè ní bèbè òhún Ó ní ti ó bá kan òké ti kó le gún-ún Ó ní ti ó bá ti fi enu so bèbè ìhín, yó ma bá ara ré ní bèbè òhún Ó ní kó di’jú Ekó di’jú Baba rè bá gba ní ìdí
Ekó bá tún bá ara rè l’órí iyorín ní ibi ti ó ti já s’óde òrun ní àkókó Ìgbàtí yó rín gàdà, ilá ló túnkó pàdé Ilá ní omo olóore òun niyí láti osù kéta, ó ní, “o rí baba àbí okò ri?” Ekó ní òun rí baba Ilá ní kínni baba fun Ekó ní ó fun òun ní àse Ekó ni òun ó tilè dán àse bàbá òun wo Ó ni, “Ilá, èwo ló ndùn é?” Ilá ni omo ni òun kò rí bí Ekó ní kí ilá ó bí ogún omo Ilá bi ogún omo Ó ní kí omo ‘kóókan m aní ogboogbón omo, ogoogún omo Ó tún pàdé ikán pèkí Ó ní “Ikán, èwo ló ndún é?” Ikán ní omo ni òun kó rí bí Ekò ní kí Ikán ó bí ogboogbòn omo, kí wón m aní àádóta, ogoogún omo nínù Béèni Ikán se bímo Ó tún pádé olóbengán Ó ní, “Olóbengán, èwo ló ndìn é?” Olóbengán ní omo ni òun kó rí bí Ekó ní kí Olóbengán bi ètàlégbéje omo, kí wón m aní ogboogbòn, ogoogóji omo Béèni dó bengán se bí mo Ekó wá njó, ó nyò, ó nkorin Ó ní: Ohùn: Baba oká ku, oká jogún oró Ègbè: Bí mo dúró Bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba Bí mo bèrè, bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba Ohún: Baba òjòlá ku, òjòlá jogún ohùn Ègbè: Bí mo dúró Bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba Bí mo bèrè, bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba Ohùn: Baba òpòló ku, òpòló j’ogún èwù ifàn Ègbè: Bí mo dúró Bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba Bí mo bèrè, bí mo wúre Ire è mi kàsàì gba